Psalms 83:17

“Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn”

Psalms 83:17 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 17 of 18 in Psalms chapter 83 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 83 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́; má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́. Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ, bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè. Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ; wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́. Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè, kí orúkọ ẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.” Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan; wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ Àgọ́ àti ti àwọn ará Iṣmaeli, ti àti ti Gebali, Ammoni àti , Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn . Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. . Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí bí o ti ṣe sí àti ní odò Kiṣoni, ẹni tí ó ṣègbé ní tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀. Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí àti , àwọn ọmọ-aládé wọn bí àti , tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní àní pápá oko tútù Ọlọ́run.” Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà, bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́. Bí iná ti í jó igbó, àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná, bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ. Fi ìtìjú kún ojú wọn, kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa. Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa: pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.

Every verse in Psalms 83

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00