Psalms 85:8

“Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí; ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.”

Psalms 85:8 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 8 of 13 in Psalms chapter 85 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 85 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa; ìwọ mú ohun ìní ọbu bọ̀ sí ipò. Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. . Ìwọ fi àwọn ìbínú rẹ sápá kan ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ. Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa, kí o sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa. Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé? Ìwọ yóò ha mú ìbínú rẹ pẹ́ yí gbogbo ìran ká? Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́, pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ? Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, Olúwa, kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ. Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí; ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye. Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa. Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀; òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn. Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run. Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́, ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde. Òdodo síwájú rẹ lọ o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Every verse in Psalms 85

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00