Romans 9:28
“Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.””
Romans 9:28 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 28 of 33 in Romans chapter 9 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Romans 9 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Òtítọ́ ni èmi ń sọ nínú , èmi kò ṣèké, ọkàn mi sì ń jẹ́ mi ní ẹ̀rí nínú Ẹ̀mí Mímọ́. Pé mo ní ìbìnújẹ́ púpọ̀, àti ìkáàánú ìgbà gbogbo ni ọkàn mi. Nítorí mo fẹ́rẹ lè gbàdúrà pé kí èmi tìkára mi kúrò lọ́dọ̀ nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara. Àwọn ẹni tí i ṣe ẹli; tí àwọn ẹni tí ìsọdọmọ í ṣe, àti ògo, àti májẹ̀mú, àti ìfúnilófin, àti ìsìn Ọlọ́run, àti àwọn ìlérí. Tí ẹni tí àwọn í ṣe, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí ti wá nípa ti ara, ẹni tí ó borí ohun gbogbo, Ọlọ́run olùbùkún láéláé. Àmín. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú ẹli wá, àwọn ni ẹli. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ , gbogbo wọn ni ọmọ. Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.” Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara ni ọmọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.” Kì í sì í ṣe kìkì èyí, ṣùgbọ́n nígbà tí pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún baba wa. Nítorí nígbà tí kò tí ì bí àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú—kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kò ṣe ti ẹni tí ń peni—a ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.” Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Jakọbu ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n ni mo kórìíra.” Ǹjẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìṣòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri! Nítorí ó wí fún pé, “Èmi ó ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣe ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò ṣe ìyọ́nú fún.” Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í ṣe ti ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe ti Ọlọ́run tí ń ṣàánú. Nítorí ìwé mímọ́ wí fún pé, “Nítorí èyí náà ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.” Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le. Ìwọ ó sì wí fún mi pé, “Kín ni ó ha tún bá ni wí sí? Nítorí ta ni ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?” Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’ ” Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí amọ̀, nínú ìṣù kan náà láti ṣe apá kan nínú ohun èlò sí ọlá, àti apá kan nínú ohun èlò sí àìlọ́lá? Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mí mọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun. Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo. Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? Bí ó ti wí pẹ̀lú ní pé, “Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ‘ènìyàn mi’, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní ‘àyànfẹ́.’ ” Yóò sì ṣe, “Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ” sì kígbe nítorí ẹli pé: “Bí iye àwọn ọmọ ẹli bá rí bí iyanrìn Òkun, apá kan ni ó gbàlà. Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.” Àti bí ti wí tẹ́lẹ̀: “Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ìbá ti dàbí , a bá sì ti sọ wá dàbí .” Ǹjẹ́ kí ni àwa ó ha wí? Pé àwọn Kèfèrí, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàlà wá ni. Ṣùgbọ́n ẹli ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo. Nítorí kí ni? Nítorí wọn kò wá a nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni pé nípa iṣẹ́ òfin. Nítorí wọn kọsẹ̀ lára òkúta ìkọ̀sẹ̀ ni. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú, ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”
Every verse in Romans 9
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.