Song of Solomon 3:6

“Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá bí ọ̀wọ̀n èéfín tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?”

Song of Solomon 3:6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 6 of 11 in Song of Solomon chapter 3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Song of Solomon 3 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ní orí ibùsùn mi ní òru mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́; mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i. Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú, ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde; èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i. Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú. “Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?” Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi, sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi. Ẹ̀yin ọmọbìnrin ẹmu, mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú. Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá bí ọ̀wọ̀n èéfín tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn íṣòwò? Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti , àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká, àwọn akọni ẹli, gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́, gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun, idà íkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀; o fi igi ṣe é. Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀, o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀. Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀, inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí. “Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin ẹmu.” Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin , kí ẹ sì wo ọba tí ó dé adé, adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

Every verse in Song of Solomon 3

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00