Song of Solomon 4:15

“Ìwọ ni ọgbà orísun, kànga omi ìyè, ìṣàn omi láti Lebanoni wá.”

Song of Solomon 4:15 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 15 of 16 in Song of Solomon chapter 4 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Song of Solomon 4 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi! Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà! Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́. Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè . Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀; olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́; kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró. Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó; ẹnu rẹ̀ dùn. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate lábẹ́ ìbòjú rẹ. Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ , tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra; lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún (1,000) àpáta kọ́, gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára. Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì. Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀ tí òjìji yóò fi fò lọ, èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá àti sí òkè kékeré tùràrí. Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi; kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ. Kí a lọ kúrò ní , ìyàwó mi, ki a lọ kúrò ní . Àwa wò láti orí òkè , láti orí òkè ti , àti téńté , láti ibi ihò àwọn kìnnìún, láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn. Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ. Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi! Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ, òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ! Ètè rẹ ń kan dídùn bí afárá oyin, ìyàwó mi; wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ. Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn . Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìsun tí a sé mọ́, orísun tí a fi èdìdì dì. Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pomegiranate ni ti òun ti àṣàyàn èso; kipiresi àti nadi, nadi àti , kalamusi àti kinamoni, àti gbogbo igi olóòórùn dídùn, òjìá àti aloe pẹ̀lú irú wọn. Ìwọ ni ọgbà orísun, kànga omi ìyè, ìṣàn omi láti wá. Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwá kí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúúsù! Fẹ́ lórí ọgbà mi, kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde. Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀ kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀.

Every verse in Song of Solomon 4

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00