Zechariah 2:1
“Mó si tún gbé ojú mi, sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ọkùnrin kan ti o mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ rẹ̀.”
Zechariah 2:1 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 1 of 13 in Zechariah chapter 2 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Zechariah 2 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Mó si tún gbé ojú mi, sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ọkùnrin kan ti o mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ rẹ̀. Mo sí wí pé, “Níbo ni ìwọ ń lọ?” O sí wí fún mí pé, “Láti wọn ẹmu, láti rí iye ìbú rẹ̀, àti iye gígùn rẹ̀.” Sì kíyèsi i, angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, angẹli mìíràn si jáde lọ pàdé rẹ̀. Ó si wí fún un pé, “Sáré, sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin yìí wí pé, ‘A ó gbé inú ẹmu bi ìlú ti kò ní odi, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn àti ohun ọ̀sìn inú rẹ̀. Olúwa wí pé: Èmi ó sì jẹ́ odi iná fún un yíká, èmi ó sì jẹ́ ògo láàrín rẹ̀.’ “Wá! Wá! Sá kúrò ni ilẹ̀ àríwá,” ni Olúwa wí, “nítorí pé bí afẹ́fẹ́ mẹ́rin ọ̀run ni mo tú yín káàkiri,” ni Olúwa wí. “Gbà ara rẹ̀ sílẹ̀, ìwọ , ìwọ tí ó ń bà ọmọbìnrin gbé.” Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Lẹ́yìn ògo rẹ̀ ni a ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kó yin: nítorí ẹni tí ó tọ́ yin, ó tọ́ ọmọ ojú rẹ̀. Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ìkógun fún ìránṣẹ́ wọn: ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi. “Kọrin kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin . Nítorí èmi ń bọ̀ àti pé èmi yóò sì gbé àárín rẹ,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò dàpọ̀ mọ́ Olúwa ní ọjọ́ náà, wọn yóò sì di ènìyàn mi, èmi yóò sì gbé àárín rẹ, ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí ọ. Olúwa yóò sì jogún ìní rẹ̀, ni ilẹ̀ mímọ́, yóò sì tún yan ẹmu. Ẹ̀ dákẹ́, gbogbo ẹran-ara níwájú Olúwa: nítorí a jí i láti ibùgbé mímọ́ rẹ̀ wá.”
Every verse in Zechariah 2
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.