Zechariah 5:8

“Ó sì wí pé, “Èyí ni ìwà búburú.” Ó sì ti sí àárín òsùwọ̀n, ó sì ju ìdérí òjé sí ẹnu rẹ̀.”

Zechariah 5:8 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 8 of 11 in Zechariah chapter 5 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Zechariah 5 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ìwé kíká ti ń fò. Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?” Èmi sì dáhùn pé, “Mo rí ìwé kíká tí ń fò; gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.” Ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀; gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀. Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò mú un jáde, Èmi yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi orúkọ mi búra èké, yóò si wà ni àárín ilé rẹ̀, yóò si rún pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀.’ ” Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì jáde lọ, ó sì wí fún mi pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wo nǹkan tí yóò jáde lọ.” Mo sì wí pé, “Kí ni nǹkan náà?” Ó sì wí pé, “Èyí ni òsùwọ̀n tí ó jáde lọ.” Ó sì wí pé, “Èyí ni àwòrán ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” Sì kíyèsi i, a gbé tálẹ́ǹtì òjé sókè, obìnrin kan sì nìyìí tí ó jókòó sí àárín àpẹẹrẹ òsùwọ̀n. Ó sì wí pé, “Èyí ni ìwà búburú.” Ó sì ti sí àárín òsùwọ̀n, ó sì ju ìdérí òjé sí ẹnu rẹ̀. Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, obìnrin méjì jáde wá, ẹ̀fúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn; nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀, wọ́n sì gbé àpẹẹrẹ òsùwọ̀n náà dé àárín méjì ayé àti ọ̀run. Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Níbo ni àwọn wọ̀nyí ń gbé òsùwọ̀n náà lọ.” Ó si wí fún mi pé, “Sí orílẹ̀-èdè láti kọ ilé fún un. Tí ó bá ṣetán, a ó sì fi ìdí rẹ̀ mulẹ̀, a o sì fi ka orí ìpìlẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.”

Every verse in Zechariah 5

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00