Zechariah 9:5
“Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù; Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi, àti Ekroni: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í. Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀, Aṣkeloni yóò sì di ahoro.”
Zechariah 9:5 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 5 of 17 in Zechariah chapter 9 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Zechariah 9 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀. Ọ̀rọ̀ Olúwa kọjú ìjà sí , Damasku ni yóò sì jẹ́ ibi ìsinmi rẹ̀; nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára ènìyàn, àti lára gbogbo ẹ̀yà ẹli. Àti pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀ àti bí o tilẹ̀ ṣe ọlọ́gbọ́n gidigidi. Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀, ó sì kó fàdákà jọ bí eruku, àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro. Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ, yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun, a ó sì fi iná jó o run. Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù; Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi, àti : nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í. Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀, Aṣkeloni yóò sì di ahoro. Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Aṣdodu, Èmi yóò sì gé ìgbéraga àwọn kúrò. Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀, àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrín eyín rẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn tó ṣẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa, wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní , àti ni yóò rí bí . Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi ká nítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri, kò sí aninilára tí yóò bori wọn mọ́: nítorí ni ìsinsin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn. Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin , hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin ẹmu. Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ: òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà; ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni , àti ẹṣin ogun kúrò ni ẹmu, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun. Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí. Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun, àti láti odò títí de òpin ayé. Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun. Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ti o ni ìrètí: àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́po méjì. Èmi ó fa le bí mo ṣe fa ọrun mi le, mo sì fi kún un, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ , sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ , mo ṣe ọ́ bí idà alágbára. Olúwa yóò sì fi ara hàn ní orí wọn; ọfà rẹ̀ yóò sì jáde lọ bí mọ̀nàmọ́ná. Olúwa Olódùmarè yóò sì fọn ìpè, Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúúsù. Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n; wọn ó sì jẹ ni run, wọn ó sì tẹ òkúta kànnàkànnà mọ́lẹ̀; wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì, wọn ó sì kún bí ọpọ́n, wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ. Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà bí agbo ènìyàn rẹ̀: nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé, tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀. Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ sì tí pọ̀! Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá, àti ọtí wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
Every verse in Zechariah 9
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.