Exodus 2:3
“Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé papirusi hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà àti òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú eèsún ni etí odò Naili.”
Exodus 2:3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 3 of 25 in Exodus chapter 2 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Exodus 2 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ó sì ṣe, ọkùnrin ará ilé kan fẹ́ ọmọbìnrin ará kan ni ìyàwó. Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tí ó rí í pé ọmọ náà rẹwà, ó gbé ọmọ náà pamọ́ fún oṣù mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé papirusi hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà àti òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú eèsún ni etí odò . Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà. Nígbà náà ni ọmọbìnrin sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò. Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárín eèsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá, ó ṣí i, ó sì rí ọmọ náà. Ọmọ náà ń sọkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é. Ó wí pé, “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ni èyí.” Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin pé, “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá. Ọmọbìnrin sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ.” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní , ó wí pé, “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.” Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, ó ri ará tí ń lu ará , ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó wo ìhín, ó wo ọ̀hún, nígbà tí kò rí ẹnìkankan, ni ó bá pa ará náà, ó sì bò ó mọ́ inú iyanrìn. Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu arákùnrin rẹ?” Ọkùnrin náà sì dáhùn pé, “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti ídàájọ́ lórí wa? Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará ?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba , ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni ọ̀ràn yìí ti di mí mọ̀.” Nígbà ti sì gbọ́ nípa èyí, ó wá ọ̀nà láti pa , ṣùgbọ́n sá kúrò ní àrọ́wọ́tó o , ó lọ sí láti máa gbé, nígbà tí ó dé bẹ̀, ó jókòó ni ẹ̀bá a kànga kan. Ó sì ṣe, àlùfáà kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn. Àwọn darandaran kan wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi. Nígbà ti àwọn ọmọbìnrin náà padà dé ọ̀dọ̀ baba wọn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tètè dé ni òní?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará kan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn darandaran, ó tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fa omi àti láti fún agbo ẹran ní omi.” Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, “Níbo ni ó wà? Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀? Ẹ pè é wá jẹun.” Mose gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi , ọmọbìnrin rẹ̀ fún láti fi ṣe aya. Ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní ṣomu, ó wí pé, “Èmi ń ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.” Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ọba kú. Àwọn ará ẹli ń kérora ní oko ẹrú wọn, wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ nítorí oko ẹrú tí wọ́n wà, igbe wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ọlọ́run gbọ́ igbe wọn, Ó sì rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú , Isaaki àti pẹ̀lú ọbu. Nítorí náà, Ọlọ́run bojú wo àwọn ará ẹli, Ó sì wà láti gbà wọ́n sílẹ̀.
Every verse in Exodus 2
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.