Isaiah 20:2

“ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu Isaiah ọmọ Amosi jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà.”

Isaiah 20:2 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 2 of 6 in Isaiah chapter 20 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Isaiah 20 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ní ọdún tí olórí ogun, tí ọba rán an, wá sí Aṣdodu, ó kọlù ú ó sì kó o— ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu ọmọ jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà. Lẹ́yìn náà ni Olúwa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi ti lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àmì àti àpẹẹrẹ sí àti Kuṣi, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọba yóò kó àwọn ìgbèkùn lọ ní ìhòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kuṣi, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí ìhòhò—bí àbùkù . Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Kuṣi tí wọ́n sì ń fi yangàn ni ẹ̀rù yóò dé bá tí a ó sì dójútì wọ́n. Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní etí Òkun yóò wí pé, ‘Wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ti gbẹ́kẹ̀lé, àwọn tí a sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ ọba ! Báwo ni a ó ṣe sálà?’ ”

Every verse in Isaiah 20

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00