Job 26:11
“Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì, ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀.”
Job 26:11 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 11 of 14 in Job chapter 26 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Job 26 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ṣùgbọ́n sì dáhùn wí pé, “Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá, báwo ní ìwọ ń ṣe gbe apá ẹni tí kò ní agbára? Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ fun ẹni tí kò ní ọgbọ́n, tàbí báwo òye rẹ to pọ to bẹ́ẹ̀? Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti ẹ̀mí ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?” “Àwọn aláìlágbára ti isà òkú wárìrì, lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run, ibi ìparun kò sí ní ibojì. Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú, ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán. Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn; àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn. Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn, ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí. Ó fi ìdè yí omi òkun ká, títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn. Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì, ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀. Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun; nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́. Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́; ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì. Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀; ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó! Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”
Every verse in Job 26
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.