Psalms 77:1

“Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́; mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.”

Psalms 77:1 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 1 of 20 in Psalms chapter 77 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 77 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́; mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi. Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú, mo wá Olúwa; ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú. Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run, mo sì kẹ́dùn; mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. . Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fi ojú ba oorun, mo dààmú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀. Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì; ọdún pípẹ́ sẹ́yìn; mo rántí orin mi ní òru. Èmi ń bá àyà mi sọ̀rọ̀, ọkàn mi sì ń ṣe àwárí jọjọ. “Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé? Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́? Ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àánú rẹ̀ ti kú lọ láéláé? Ìlérí rẹ̀ ha kùnà títí ayé? Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú? Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” . Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi, pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”. Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́. Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo, pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ. Ọlọ́run, ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́. Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa? Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu; ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà, àwọn ọmọ ọbu àti ẹfu. . Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run, nígbà tí àwọn omi rí ọ, ẹ̀rù bà wọ́n, nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀. Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀, àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn; ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú. Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé; ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì. Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun, ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá, nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nípa ọwọ́ àti .

Every verse in Psalms 77

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00