Psalms 82:6

““Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”; ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’”

Psalms 82:6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 6 of 8 in Psalms chapter 82 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 82 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá, ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”. “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú? Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba; ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára. Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní; gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú. “Wọn kò mọ̀ ohun kankan, wọn kò lóye ohun kankan. Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn; à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé. “Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”; ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán; ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.” Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé, nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.

Every verse in Psalms 82

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00