2 Samuel 9:5

“Dafidi ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Makiri ọmọ Ammieli láti Lo-Debari wá.”

2 Samuel 9:5 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 5 of 13 in 2 Samuel chapter 9 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

2 Samuel 9 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Dafidi sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí . Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé , orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Ṣiba, wọ́n sì pè é wá sọ́dọ̀ , ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Ṣiba bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni.” Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé síbẹ̀, kí èmi ṣe oore Ọlọ́run fún un?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Jonatani ní ọmọ kan síbẹ̀ tó ya arọ.” Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé , ọmọ , ní Lo-.” Dafidi ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé ọmọ láti Lo- wá. Mefiboṣeti ọmọ ọmọ sì tọ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un. Dafidi sì wí pé, “Mefiboṣeti!” Òun sì dáhùn wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!” Dafidi sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé baba rẹ fún ọ, ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” Mefiboṣeti sì tẹríba, ó sì wí pé, “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi.” Ọba sì pe Ṣiba ìránṣẹ́ , ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti , àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ. Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ro ilẹ̀ náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkórè wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí oúnjẹ jẹ, ṣùgbọ́n ṣeti ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣiba sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.) Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti ṣeti, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.” Mefiboṣeti sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ . Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Ṣiba ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún ṣeti. Mefiboṣeti sì ń gbé ní ẹmu, òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ ọba; òun sì yarọ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.

Every verse in 2 Samuel 9

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00